30 Nígbà náà, àmì Ọmọ èèyàn máa fara hàn ní ọ̀run, ìbànújẹ́ máa mú kí gbogbo àwọn ẹ̀yà tó wà ní ayé lu ara wọn,+ wọ́n sì máa rí Ọmọ èèyàn+ tó ń bọ̀ lórí àwọsánmà* ojú ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+
14 Lẹ́yìn náà, wò ó! mo rí ìkùukùu* funfun kan, ẹnì kan tó rí bí ọmọ èèyàn jókòó sórí ìkùukùu* náà,+ ó dé adé wúrà, dòjé tí ẹnu rẹ̀ mú sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.