ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 19:28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Jésù sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, nígbà àtúndá, tí Ọmọ èèyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tẹ̀ lé mi máa jókòó sórí ìtẹ́ méjìlá (12), ẹ sì máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.+

  • Lúùkù 22:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 mo sì bá yín dá májẹ̀mú fún ìjọba kan, bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú,+

  • Ìfihàn 1:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 tó sì mú ká di ìjọba kan,+ àlùfáà+ fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—àní, òun ni kí ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.

  • Ìfihàn 3:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Màá jẹ́ kí ẹni tó bá ṣẹ́gun+ jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi,+ bí èmi náà ṣe ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó+ pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀.

  • Ìfihàn 5:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Wọ́n sì ń kọ orin tuntun+ kan pé: “Ìwọ ló yẹ kó gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, torí pé wọ́n pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn èèyàn fún Ọlọ́run+ látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n* àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè,+ 10 o mú kí wọ́n di ìjọba kan+ àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa,+ wọ́n sì máa ṣàkóso bí ọba+ lé ayé lórí.”

  • Ìfihàn 20:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Mo rí àwọn ìtẹ́, a sì fún àwọn tó jókòó sórí wọn ní agbára láti ṣèdájọ́. Kódà, mo rí ọkàn* àwọn tí wọ́n pa* torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jésù, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko náà tàbí ère rẹ̀, tí wọn ò sì gba àmì náà síwájú orí wọn àti ọwọ́ wọn.+ Wọ́n pa dà wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kristi+ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́