-
Diutarónómì 5:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n sún ọ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,+ 10 àmọ́ tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi títí dé ẹgbẹ̀rún ìran wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.
-
-
Nehemáyà 1:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Mo sọ pé: “Ìwọ Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+
-