-
Lúùkù 19:43, 44Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Torí pé àwọn ọjọ́ máa dé bá ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ máa fi àwọn igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ po, wọ́n máa yí ọ ká, wọ́n á sì dó tì ọ́* yí ká.+ 44 Wọ́n máa fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tó wà nínú rẹ mọ́lẹ̀,+ wọn ò sì ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ,+ torí pé o ò fi òye mọ àkókò tí a máa bẹ̀ ọ́ wò.”
-