-
Hébérù 9:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àmọ́, nígbà tí Kristi dé bí àlùfáà àgbà àwọn ohun rere tó ti ṣẹlẹ̀, ó gba inú àgọ́ tó tóbi jù, tó sì jẹ́ pípé jù, tí wọn ò fi ọwọ́ ṣe, ìyẹn tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí. 12 Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni,+ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀* àìnípẹ̀kun fún wa.+
-
-
Hébérù 10:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Lẹ́yìn tó kọ́kọ́ sọ pé: “O ò fẹ́ àwọn ẹbọ, ọrẹ, odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, o ò sì fọwọ́ sí i”—àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú, bí Òfin ṣe sọ— 9 ó wá sọ pé: “Wò ó! Mo ti dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”+ Ó fi òpin sí èyí àkọ́kọ́ kó lè fìdí ìkejì múlẹ̀. 10 Nípasẹ̀ “ìfẹ́” yìí,+ a ti fi ara Jésù Kristi tó fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé sọ wá di mímọ́.+
-