16 Ẹni tó ń bọ̀ láti gbéjà kò ó máa ṣe ohun tó wù ú, kò sì ní sẹ́ni tó máa dúró níwájú rẹ̀. Ó máa dúró ní ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́,*+ agbára láti pani run sì máa wà ní ọwọ́ rẹ̀.
41 Ó tún máa wọ ilẹ̀ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́,*+ a sì máa mú ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kọsẹ̀. Àmọ́ àwọn tó máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nìyí: Édómù, Móábù àti èyí tó ṣe pàtàkì jù lára àwọn ọmọ Ámónì.