-
Dáníẹ́lì 2:40-42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
40 “Ní ti ìjọba kẹrin, ó máa le bí irin.+ Torí bí irin ṣe ń fọ́ gbogbo nǹkan míì túútúú, tó sì ń lọ̀ ọ́, àní, bí irin ṣe ń rún nǹkan wómúwómú, ó máa fọ́ gbogbo èyí túútúú, ó sì máa rún un wómúwómú.+
41 “Bí o sì ṣe rí i pé àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ ti amọ̀kòkò àti apá kan irin, ìjọba náà máa pínyà, àmọ́ ó ṣì máa le bí irin lápá kan, bí o ṣe rí i pé irin náà dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírọ̀. 42 Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ sì ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba náà ṣe máa lágbára lápá kan, tí kò sì ní lágbára lápá kan.
-