32 Ní ọdún kejì Pékà ọmọ Remaláyà ọba Ísírẹ́lì, Jótámù+ ọmọ Ùsáyà+ ọba Júdà jọba. 33 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jẹ́rúṣà ọmọ Sádókù.+ 34 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà bí Ùsáyà bàbá rẹ̀ ti ṣe.+