34 “Màá gbèjà ìlú yìí,+ màá sì gbà á sílẹ̀ nítorí orúkọ mi+
Àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”’”+
35 Ní òru ọjọ́ yẹn, áńgẹ́lì Jèhófà jáde lọ, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọkùnrin nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà.+ Nígbà tí àwọn èèyàn jí láàárọ̀ kùtù, wọ́n rí òkú nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+