10 Ní ọdún kẹtàdínlógójì Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni ó sì fi ṣàkóso. 11 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Ó ń dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà nìṣó.