29 “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú àwọn ọjọ́ yẹn, oòrùn máa ṣókùnkùn,+ òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀, àwọn ìràwọ̀ máa já bọ́ láti ọ̀run, a sì máa mi àwọn agbára ọ̀run.+
25 “Bákan náà, àwọn àmì máa wà nínú oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀,+ ìdààmú sì máa bá àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé, wọn ò ní mọ ọ̀nà àbáyọ torí ariwo omi òkun àti bó ṣe ń ru gùdù.
2 Ó ṣí àbáwọlé* ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, èéfín sì jáde látinú ọ̀gbun náà bí èéfín iná ìléru ńlá, èéfín tó ń jáde látinú ọ̀gbun náà sì mú kí oòrùn ṣókùnkùn+ bẹ́ẹ̀ náà sì ni afẹ́fẹ́.