11 Sọ fún wọn pé, ‘“Bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “inú mi ò dùn sí ikú ẹni burúkú,+ bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí ìwà rẹ̀ pa dà,+ kó sì máa wà láàyè.+ Ẹ yí pa dà, ẹ yí ìwà búburú yín pa dà,+ ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú ni, ilé Ísírẹ́lì?”’+
7 Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti kẹ̀yìn sí àwọn ìlànà mi, ẹ kò sì tẹ̀ lé wọn.+ Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.