27 Ìjọsìn* tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí+ àti àwọn opó+ nínú ìpọ́njú wọn,+ ká sì máa pa ara wa mọ́ láìní àbààwọ́n nínú ayé.+
4 Wò ó! Owó iṣẹ́ tí ẹ ò san fún àwọn òṣìṣẹ́ tó kórè oko yín ń ké jáde ṣáá, igbe tí àwọn olùkórè ń ké fún ìrànwọ́ sì ti dé etí Jèhófà* Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+