19 Lẹ́yìn tó lọ síwájú díẹ̀ sí i, ó rí Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe,+ 20 ó sì pè wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Torí náà, wọ́n fi Sébédè bàbá wọn sílẹ̀ sínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀ lé e.