20 Ó tún sọ pé: “Ohun tó ń tinú èèyàn jáde ló ń sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 21 Torí láti inú, láti ọkàn àwọn èèyàn,+ ni àwọn èrò burúkú ti ń wá: ìṣekúṣe, olè jíjà, ìpànìyàn, 22 àwọn ìwà àgbèrè, ojúkòkòrò, àwọn ìwà burúkú, ẹ̀tàn, ìwà àìnítìjú, ojú tó ń ṣe ìlara, ọ̀rọ̀ òdì, ìgbéraga àti ìwà òmùgọ̀.