-
1 Kíróníkà 3:10-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ọmọ Sólómọ́nì ni Rèhóbóámù;+ ọmọ* rẹ̀ ni Ábíjà,+ ọmọ rẹ̀ ni Ásà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jèhóṣáfátì,+ 11 ọmọ rẹ̀ ni Jèhórámù,+ ọmọ rẹ̀ ni Ahasáyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jèhóáṣì,+ 12 ọmọ rẹ̀ ni Amasááyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Asaráyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Jótámù,+ 13 ọmọ rẹ̀ ni Áhásì,+ ọmọ rẹ̀ ni Hẹsikáyà,+ ọmọ rẹ̀ ni Mánásè,+ 14 ọmọ rẹ̀ ni Ámọ́nì,+ ọmọ rẹ̀ ni Jòsáyà.+ 15 Àwọn ọmọ Jòsáyà ni Jóhánánì àkọ́bí, ìkejì ni Jèhóákímù,+ ìkẹta ni Sedekáyà,+ ìkẹrin ni Ṣálúmù. 16 Ọmọ* Jèhóákímù ni Jekonáyà,+ Sedekáyà sì ni ọmọ rẹ̀. 17 Àwọn ọmọ Jekonáyà ẹlẹ́wọ̀n ni Ṣéálítíẹ́lì, 18 Málíkírámù, Pedáyà, Ṣẹ́násà, Jekamáyà, Hóṣámà àti Nedabáyà. 19 Àwọn ọmọ Pedáyà ni Serubábélì+ àti Ṣíméì; àwọn ọmọ Serubábélì sì ni Méṣúlámù àti Hananáyà (Ṣẹ́lómítì ni arábìnrin wọn);
-
-
2 Kíróníkà 14:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Níkẹyìn, Ábíjà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì;+ Ásà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. Nígbà ayé rẹ̀, ilẹ̀ náà ní àlàáfíà fún ọdún mẹ́wàá.
-