Lúùkù 6:27, 28 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 27 “Àmọ́ mò ń sọ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fetí sílẹ̀ pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra yín,+ 28 ẹ máa súre fún àwọn tó ń gégùn-ún fún yín, kí ẹ máa gbàdúrà fún àwọn tó ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.+ Ìṣe 7:60 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 60 Lẹ́yìn náà, ó kúnlẹ̀, ó sì fi ohùn líle ké jáde pé: “Jèhófà,* má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.”+ Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó sùn nínú ikú. Róòmù 12:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Ẹ máa súre fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni;+ ẹ máa súre, ẹ má sì máa ṣépè.+
27 “Àmọ́ mò ń sọ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fetí sílẹ̀ pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ máa ṣe rere sí àwọn tó kórìíra yín,+ 28 ẹ máa súre fún àwọn tó ń gégùn-ún fún yín, kí ẹ máa gbàdúrà fún àwọn tó ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.+
60 Lẹ́yìn náà, ó kúnlẹ̀, ó sì fi ohùn líle ké jáde pé: “Jèhófà,* má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.”+ Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó sùn nínú ikú.