-
Lúùkù 12:22-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìdí nìyẹn tí mo fi ń sọ fún yín pé, ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ 23 Torí ẹ̀mí* níye lórí ju oúnjẹ lọ, ara sì níye lórí ju aṣọ lọ. 24 Ẹ wo àwọn ẹyẹ ìwò: Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í sì í kárúgbìn; wọn ò ní abà tàbí ilé ìkẹ́rùsí; síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn.+ Ṣé ẹ ò wá níye lórí gan-an ju àwọn ẹyẹ lọ ni?+ 25 Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́* kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn? 26 Torí náà, tí ẹ ò bá lè ṣe ohun tó kéré bí èyí, kí ló wá dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tó ṣẹ́ kù?+ 27 Ẹ ronú nípa bí àwọn òdòdó lílì ṣe ń dàgbà: Wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú;* àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí.+ 28 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko inú pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì jù sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?
-