-
Máàkù 6:53-56Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
53 Nígbà tí wọ́n sọdá sórí ilẹ̀, wọ́n dé Jẹ́nẹ́sárẹ́tì, wọ́n sì dá ọkọ̀ náà ró sí tòsí.+ 54 Àmọ́ gbàrà tí wọ́n jáde nínú ọkọ̀ ojú omi náà, àwọn èèyàn dá a mọ̀. 55 Wọ́n sáré yí ká gbogbo agbègbè yẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn tó ń ṣàìsàn wá lórí ibùsùn síbi tí wọ́n gbọ́ pé ó wà. 56 Níbikíbi tó bá sì ti wọ àwọn abúlé, ìlú tàbí ìgbèríko, wọ́n máa gbé àwọn aláìsàn sí àwọn ibi tí wọ́n ti ń tajà, wọ́n á sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí wọ́n fọwọ́ kan wajawaja etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán.+ Ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá.
-