14 Ẹ sì sọ pé, ‘Kí nìdí?’ Ìdí ni pé Jèhófà ti ṣe ẹlẹ́rìí láàárín ìwọ àti aya ìgbà èwe rẹ tí o hùwà àìṣòótọ́ sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ẹnì kejì rẹ, òun sì ni ìyàwó rẹ tí o bá dá májẹ̀mú.*+
32 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tí kò bá jẹ́ torí ìṣekúṣe,* lè mú kí obìnrin náà ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ obìnrin tí wọ́n ti kọ̀ sílẹ̀ ti ṣe àgbèrè.+
11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè,+ ó ti da obìnrin náà, 12 tí obìnrin kan bá sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, lẹ́yìn tó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó ti ṣe àgbèrè.”+
3 Torí náà, nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè, a ó pè é ní alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+ Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin rẹ̀, kì í sì í ṣe alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+