-
Máàkù 11:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí wọ́n so sí ẹnu ilẹ̀kùn, níta lójú ọ̀nà, wọ́n sì tú u.+ 5 Àmọ́ àwọn kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀ sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?” 6 Ohun tí Jésù sọ fún wọn gẹ́lẹ́ ni wọ́n fi dá wọn lóhùn, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.
-
-
Lúùkù 19:32-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Torí náà, àwọn tó rán níṣẹ́ lọ, wọ́n sì rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́.+ 33 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn tó ni ín sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn?” 34 Wọ́n sọ pé: “Olúwa fẹ́ lò ó.” 35 Wọ́n wá mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n ju aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì mú kí Jésù jókòó sórí rẹ̀.+
-