45 Àmọ́ tí ẹrú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi ò tètè dé,’ tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, tó ń jẹ, tó ń mu, tó sì mutí yó,+ 46 ọ̀gá ẹrú yẹn máa dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀ àti wákàtí tí kò mọ̀, ó máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́, ó sì máa kà á mọ́ àwọn aláìṣòótọ́.