-
Mátíù 18:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Torí náà, tí ọwọ́ rẹ tàbí ẹsẹ̀ rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní aláàbọ̀ ara tàbí ní arọ ju kí a jù ọ́ sínú iná àìnípẹ̀kun+ pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì tàbí ẹsẹ̀ méjèèjì. 9 Bákan náà, tí ojú rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní olójú kan ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà* oníná+ pẹ̀lú ojú méjèèjì.
-