Máàkù 14:36 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 36 Ó sì sọ pé: “Ábà,* Bàbá,+ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, àmọ́ ohun tí ìwọ fẹ́.”+ Lúùkù 22:42 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 42 ó ní: “Baba, tí o bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Àmọ́, ìfẹ́ rẹ ni kó ṣẹ, kì í ṣe tèmi.”+ Jòhánù 5:30 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 30 Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. Ohun tí mò ń gbọ́ ni mo fi ń ṣèdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi,+ torí kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.+ Jòhánù 6:38 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 38 torí mi ò sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run+ kí n lè ṣe ìfẹ́ ara mi, ṣùgbọ́n láti ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi.+ Hébérù 10:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 ó wá sọ pé: “Wò ó! Mo ti dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”+ Ó fi òpin sí èyí àkọ́kọ́ kó lè fìdí ìkejì múlẹ̀.
36 Ó sì sọ pé: “Ábà,* Bàbá,+ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, àmọ́ ohun tí ìwọ fẹ́.”+
30 Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. Ohun tí mò ń gbọ́ ni mo fi ń ṣèdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi,+ torí kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.+