-
Máàkù 15:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ kí wọ́n lè pinnu ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa mú.+
-
-
Jòhánù 19:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun kan Jésù mọ́gi tán, wọ́n mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, wọ́n pín in sí mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, wọ́n tún mú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà ò ní ojú rírán, ṣe ni wọ́n hun ún látòkè délẹ̀. 24 Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká ya á, àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi kèké pinnu ti ẹni tó máa jẹ́.”+ Èyí jẹ́ torí kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ pé: “Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.”+ Àwọn ọmọ ogun náà ṣe àwọn nǹkan yìí lóòótọ́.
-