-
Máàkù 15:45-47Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Torí náà, lẹ́yìn tí ọ̀gágun náà ti fi dá a lójú, ó gbà kí Jósẹ́fù máa gbé òkú náà lọ. 46 Lẹ́yìn tó ra aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, tó sì gbé e sọ̀ kalẹ̀, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa náà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* kan+ tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta; ó wá yí òkúta sí ẹnu ọ̀nà ibojì náà.+ 47 Àmọ́ Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè kò yéé wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.+
-