-
Mátíù 4:1-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ẹ̀mí wá darí Jésù lọ sínú aginjù kí Èṣù+ lè dán an wò.+ 2 Lẹ́yìn tó ti gbààwẹ̀ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á. 3 Adánniwò náà+ wá bá a, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.” 4 Àmọ́ ó dáhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé: ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà* jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.’”+
5 Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí ìlú mímọ́,+ ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì,+ 6 ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ’ àti pé ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+ 7 Jésù sọ fún un pé: “A tún ti kọ ọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+
8 Èṣù tún mú un lọ sí òkè kan tó ga lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.+ 9 Ó sọ fún un pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” 10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+
-
-
Lúùkù 4:1-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ kún inú Jésù, ó sì kúrò ní Jọ́dánì, ẹ̀mí wá darí rẹ̀ káàkiri nínú aginjù+ 2 fún ogójì (40) ọjọ́, Èṣù sì dán an wò.+ Kò jẹ nǹkan kan láwọn ọjọ́ yẹn, torí náà, lẹ́yìn àwọn ọjọ́ náà, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á. 3 Ni Èṣù bá sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún òkúta yìí pé kó di búrẹ́dì.” 4 Àmọ́ Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè.’”+
5 Ó wá mú un gòkè, ó sì fi gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí à ń gbé hàn án lójú ẹsẹ̀.+ 6 Èṣù wá sọ fún un pé: “Gbogbo àṣẹ yìí àti ògo wọn ni màá fún ọ, torí a ti fi lé mi lọ́wọ́,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì wù mí ni màá fún. 7 Torí náà, tí o bá jọ́sìn níwájú mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo rẹ̀ máa jẹ́ tìẹ.” 8 Jésù dá a lóhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+
9 Lẹ́yìn náà, ó mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ láti ibí yìí,+ 10 torí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, pé kí wọ́n pa ọ́ mọ́’ 11 àti pé, ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+ 12 Jésù dá a lóhùn pé: “A sọ ọ́ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+ 13 Torí náà, lẹ́yìn tí Èṣù dán an wò tán, ó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ títí di ìgbà míì tó wọ̀.+
-