28 Nígbà tó dé òdìkejì, ní agbègbè àwọn ará Gádárà, àwọn ọkùnrin méjì tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì* pàdé rẹ̀.+ Wọ́n burú gan-an débi pé kò sẹ́ni tó láyà láti gba ọ̀nà yẹn kọjá.
26 Wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté tó wà ní agbègbè àwọn ará Gérásà,+ èyí tó wà ní òdìkejì Gálílì. 27 Bí Jésù ṣe sọ̀ kalẹ̀, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu pàdé rẹ̀ látinú ìlú náà. Ó pẹ́ tí kò ti wọṣọ, kì í sì í gbé inú ilé, àárín àwọn ibojì* ló ń gbé.+