-
Lúùkù 8:35-37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Torí náà, àwọn èèyàn jáde lọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lára rẹ̀, ó ti wọṣọ, orí rẹ̀ sì ti wálé, ó jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù, ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 36 Àwọn tí wọ́n rí i ròyìn fún wọn nípa bí ara ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà ṣe yá. 37 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti agbègbè àwọn ará Gérásà ní àyíká ibẹ̀ wá sọ fún Jésù pé kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn, torí pé ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Torí náà, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kó lè máa lọ.
-