14 Jésù wá pa dà sí Gálílì+ nínú agbára ẹ̀mí. Ìròyìn rere nípa rẹ̀ sì tàn káàkiri gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká. 15 Bákan náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, gbogbo èèyàn sì ń bọlá fún un.
8Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó ń rin ìrìn àjò láti ìlú dé ìlú àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.+ Àwọn Méjìlá náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀,