-
Lúùkù 8:45-48Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Jésù wá sọ pé: “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn ń sọ pé àwọn kọ́, Pétérù sọ pé: “Olùkọ́, àwọn èrò ń há ọ mọ́, wọ́n sì ń fún mọ́ ọ.”+ 46 Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹnì kan fọwọ́ kàn mí, torí mo mọ̀ pé agbára+ jáde lára mi.” 47 Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun ò lè fara pa mọ́ mọ́, ó wá, jìnnìjìnnì bò ó, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sọ ohun tó mú kí òun fọwọ́ kàn án níwájú gbogbo èèyàn àti bí ara òun ṣe yá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 48 Àmọ́ ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà.”+
-