-
1 Àwọn Ọba 22:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nítorí náà, ó sọ pé: “Mo rí i tí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tú ká lórí àwọn òkè,+ bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn yìí kò ní ọ̀gá. Kí kálukú pa dà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’”
-
-
Ìsíkíẹ́lì 34:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Wọ́n wá fọ́n ká torí kò sí olùṣọ́ àgùntàn;+ wọ́n fọ́n ká, wọ́n sì di oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 34:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 ‘“Bí mo ti ń bẹ láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “torí pé àwọn àgùntàn mi ti di ẹran tí wọ́n fẹ́ pa, tí wọ́n sì ti di oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó, torí pé kò sí olùṣọ́ àgùntàn kankan, tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò sì wá àwọn àgùntàn mi; àmọ́ tí wọ́n ń bọ́ ara wọn, tí wọn ò sì bọ́ àwọn àgùntàn mi,”’
-