ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 14:15-21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ; jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 16 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wọn ò nílò kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” 17 Wọ́n sọ fún un pé: “A ò ní nǹkan kan níbí àfi búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì.” 18 Ó sọ pé: “Ẹ mú un wá síbí fún mi.” 19 Ó wá sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre,+ lẹ́yìn tó bu búrẹ́dì náà, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà. 20 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+ 21 Àwọn tó jẹun tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.+

  • Lúùkù 9:12-17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ọjọ́ ti ń lọ. Àwọn méjìlá náà wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ní kí àwọn èrò náà máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé àti ìgbèríko tó wà ní àyíká, kí wọ́n lè ríbi dé sí, kí wọ́n sì lè rí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ, torí ibi tó dá la wà yìí.”+ 13 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.”+ Wọ́n sọ pé: “A ò ní ju búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì, àfi bóyá tí àwa fúnra wa bá lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn èèyàn yìí.” 14 Ní tòótọ́, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin ni wọ́n. Àmọ́ ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ní kí wọ́n jókòó ní àwùjọ-àwùjọ, kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta (50) èèyàn.” 15 Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ní kí gbogbo wọn jókòó. 16 Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre sórí wọn. Ó wá bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n gbé e síwájú àwọn èrò náà. 17 Torí náà, gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́