-
Mátíù 15:3-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tẹ àṣẹ Ọlọ́run lójú torí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín?+ 4 Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ’+ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’+ 5 Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ̀bùn tí mo yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,”+ 6 kò yẹ kó bọlá fún bàbá rẹ̀ rárá.’ Ẹ ti wá sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín.+
-