-
Mátíù 15:15-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Pétérù sọ pé: “La àpèjúwe náà yé wa.” 16 Ló bá sọ pé: “Ṣé kò tíì yé ẹ̀yin náà ni?+ 17 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ohunkóhun tó bá wọ ẹnu máa ń gba inú ikùn, tí a sì máa yà á jáde sínú kòtò ẹ̀gbin? 18 Àmọ́ ohunkóhun tó bá ń ti ẹnu jáde, inú ọkàn ló ti ń wá, àwọn nǹkan yẹn ló sì ń sọ èèyàn di aláìmọ́.+ 19 Bí àpẹẹrẹ, inú ọkàn ni àwọn èrò burúkú ti ń wá,+ irú bí: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe,* olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ọ̀rọ̀ òdì. 20 Àwọn nǹkan yìí ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́; àmọ́ èèyàn ò lè di aláìmọ́ tó bá jẹun láìwẹ* ọwọ́.”
-