-
Mátíù 16:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àwọn Farisí àti àwọn Sadusí wá bá a, wọ́n ní kó fi àmì kan han àwọn láti ọ̀run, kí wọ́n lè dá an wò.+ 2 Ó dá wọn lóhùn pé: “Tó bá di ìrọ̀lẹ́, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ máa dáa, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná,’ 3 tó bá sì di àárọ̀, ẹ máa ń sọ pé ‘Ojú ọjọ́ máa tutù, òjò sì máa rọ̀ lónìí, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná, àmọ́ ó ṣú dùdù.’ Ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ ojú ọjọ́, àmọ́ ẹ ò lè túmọ̀ àwọn àmì àkókò.
-