-
Mátíù 8:28, 29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Nígbà tó dé òdìkejì, ní agbègbè àwọn ará Gádárà, àwọn ọkùnrin méjì tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì* pàdé rẹ̀.+ Wọ́n burú gan-an débi pé kò sẹ́ni tó láyà láti gba ọ̀nà yẹn kọjá. 29 Wò ó! wọ́n kígbe pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Ọmọ Ọlọ́run?+ Ṣé o wá síbí láti fìyà jẹ wá+ kí àkókò tó tó ni?”+
-