20 Ó sọ fún wọn pé: “Torí ìgbàgbọ́ yín kéré ni. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ, kò sì sí ohun tí ẹ ò ní lè ṣe.”+
23 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ tí kò sì ṣiyèméjì nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ tó ní ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun sọ máa rí bẹ́ẹ̀, ó máa rí bẹ́ẹ̀ fún un.+
6 Olúwa wá sọ pé: “Tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún igi mọ́líbẹ́rì dúdú yìí pé, ‘Fà tu, kí o sì lọ fìdí sọlẹ̀ sínú òkun!’ ó sì máa gbọ́ tiyín.+
9 Ọkùnrin yìí ń fetí sí Pọ́ọ̀lù bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹjú mọ́ ọn, tó sì rí i pé ó ní ìgbàgbọ́ pé òun lè rí ìwòsàn,+10 ó gbóhùn sókè pé: “Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ.” Ọkùnrin náà fò sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.+