-
Mátíù 18:1-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ní wákàtí yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sí tòsí Jésù, wọ́n sì bi í pé: “Ní tòótọ́, ta ló tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run?”+ 2 Torí náà, ó pe ọmọ kékeré kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó mú un dúró ní àárín wọn, 3 ó sì sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé ẹ yí pa dà,* kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọdé,+ ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run.+ 4 Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tó tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run;+ 5 ẹnikẹ́ni tó bá sì gba irú ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ mi gba èmi náà.
-
-
Lúùkù 9:46-48Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
46 Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù nínú wọn.+ 47 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn, ó wá mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, 48 ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ Torí ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi.”+
-