-
Mátíù 8:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn èèyàn mú ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ọ̀rọ̀ ló fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì wo gbogbo àwọn tó ń jìyà sàn,
-
-
Lúùkù 4:40, 41Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
40 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ń wọ̀, gbogbo àwọn tí èèyàn wọn ń ṣàìsàn, tí wọ́n ní oríṣiríṣi àrùn, mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó ń wò wọ́n sàn.+ 41 Àwọn ẹ̀mí èṣù tún jáde lára ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì ń sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ Àmọ́ ó bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀,+ torí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.+
-