-
Mátíù 20:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) náà sí ẹ̀gbẹ́ kan láwọn nìkan, ó sì sọ fún wọn lójú ọ̀nà pé:+ 18 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un,+ 19 wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n nà án, kí wọ́n sì kàn án mọ́gi;+ a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+
-
-
Lúùkù 18:31-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Ó wá pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, gbogbo nǹkan tí a tipasẹ̀ àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ nípa Ọmọ èèyàn ló sì máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀.*+ 32 Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+ wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n á hùwà àfojúdi sí i, wọ́n á sì tutọ́ sí i lára.+ 33 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì nà án, wọ́n máa pa á,+ àmọ́ ó máa dìde ní ọjọ́ kẹta.”+
-