-
Mátíù 21:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Ó tajú kán rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan létí ọ̀nà, ó sì lọ sí ìdí rẹ̀, àmọ́ kò rí nǹkan kan lórí rẹ̀ àfi ewé,+ ó wá sọ fún un pé: “Kí èso kankan má so lórí rẹ mọ́ títí láé.”+ Igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì rọ lójú ẹsẹ̀. 20 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló mú kí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà rọ lójú ẹsẹ̀?”+
-