32 Kí ni kí n tún sọ? Torí àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì,+ Bárákì,+ Sámúsìn,+ Jẹ́fútà,+ Dáfídì,+ títí kan Sámúẹ́lì+ àti àwọn wòlíì yòókù.
37 Wọ́n sọ wọ́n lókùúta,+ wọ́n dán wọn wò, wọ́n fi ayùn rẹ́ wọn sí méjì,* wọ́n fi idà pa wọ́n,+ wọ́n rìn kiri pẹ̀lú awọ àgùntàn àti awọ ewúrẹ́ lọ́rùn,+ nígbà tí wọ́n ṣaláìní, nínú ìpọ́njú,+ nígbà tí wọ́n hùwà àìdáa sí wọn;+