-
Ìṣe 4:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 kí gbogbo yín àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì yáa mọ̀ pé ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì,+ ẹni tí ẹ kàn mọ́gi,*+ àmọ́ tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú ikú,+ ni ọkùnrin yìí fi dúró níbí pẹ̀lú ara yíyá gágá níwájú yín. 11 Jésù yìí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin kọ́lékọ́lé ò kà sí tó ti wá di olórí òkúta igun ilé.’*+
-