-
Mátíù 22:15-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Àwọn Farisí wá lọ gbìmọ̀ pọ̀, kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un.+ 16 Torí náà, wọ́n rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn sí i, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù,+ wọ́n sọ pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́, o kì í wá ojúure ẹnikẹ́ni, torí kì í ṣe ìrísí àwọn èèyàn lò ń wò. 17 Torí náà, sọ fún wa, kí lèrò rẹ? Ṣé ó bófin mu* láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?” 18 Àmọ́ Jésù mọ èrò burúkú wọn, ó sọ pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè, kí ló dé tí ẹ̀ ń dán mi wò? 19 Ẹ fi ẹyọ owó tí ẹ fi ń san owó orí hàn mí.” Wọ́n mú owó dínárì* kan wá fún un. 20 Ó sì sọ fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta nìyí?” 21 Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì ni.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìyẹn, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì lọ.
-
-
Lúùkù 20:20-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Lẹ́yìn tí wọ́n ṣọ́ ọ dáadáa, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tí wọ́n háyà ní bòókẹ́lẹ́ jáde pé kí wọ́n díbọ́n pé àwọn jẹ́ olódodo, kí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un,+ kí wọ́n lè fà á lé ìjọba lọ́wọ́, kí wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ gómìnà. 21 Wọ́n bi í pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé o máa ń sọ̀rọ̀, o sì máa ń kọ́ni lọ́nà tó tọ́, o kì í ṣe ojúsàájú rárá, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́: 22 Ṣé ó bófin mu* fún wa láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?” 23 Àmọ́ ó rí i pé alárèékérekè ni wọ́n, ó wá sọ fún wọn pé: 24 “Ẹ fi owó dínárì* kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ta ló wà níbẹ̀?” Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì.” 25 Ó sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ rí i dájú pé ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,+ àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 26 Wọn ò wá lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un níwájú àwọn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀, ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì dákẹ́.
-