-
Lúùkù 5:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Wò ó! àwọn ọkùnrin kan fi ibùsùn gbé ọkùnrin kan tó ní àrùn rọpárọsẹ̀, wọ́n sì ń gbìyànjú láti gbé e wọlé, kí wọ́n lè gbé e síwájú Jésù.+ 19 Torí náà, nígbà tí wọn ò rí ọ̀nà gbé e wọlé torí àwọn èrò náà, wọ́n gun orí òrùlé, wọ́n sì fi ibùsùn náà sọ̀ ọ́ kalẹ̀ gba àárín ohun tí wọ́n fi bo ilé náà, wọ́n gbé e sọ̀ kalẹ̀ sí àárín àwọn tó wà níwájú Jésù.
-