10 Ó wá sọ fún wọn pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè+ àti ìjọba sí ìjọba.+11 Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì;+ ẹ máa rí àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì tó lágbára sì máa wà láti ọ̀run.
6 Mo gbọ́ tí nǹkan kan dún bí ohùn láàárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ó sọ pé: “Òṣùwọ̀n kúọ̀tì* àlìkámà* kan fún owó dínárì*+ kan àti òṣùwọ̀n kúọ̀tì mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.”+
8 Sì wò ó! mo rí ẹṣin ràndánràndán kan, Ikú ni orúkọ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. Isà Òkú* sì ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí. A sì fún wọn ní àṣẹ lórí ìdá mẹ́rin ayé pé kí wọ́n fi idà gígùn, ìyàn,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti àwọn ẹran inú igbó pani.+