2 Wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin kan bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní àrùn rọpárọsẹ̀, ó sì dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn. Nígbà tó rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní, Jésù sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Mọ́kàn le, ọmọ! A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+
47 Torí èyí, mò ń sọ fún ọ, bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tiẹ̀ pọ̀,* a dárí wọn jì í,+ torí ó ní ìfẹ́ púpọ̀. Àmọ́ ẹni tí a dárí díẹ̀ jì ní ìfẹ́ díẹ̀.” 48 Ó wá sọ fún un pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+