ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 4:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Torí náà, lọ, màá wà pẹ̀lú rẹ bí o ṣe ń sọ̀rọ̀,* màá sì kọ́ ọ ní ohun tí o máa sọ.”+

  • Mátíù 10:19, 20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Àmọ́ tí wọ́n bá ti fà yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn;+ 20 torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.+

  • Lúùkù 12:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Tí wọ́n bá mú yín wọlé síwájú ibi táwọn èèyàn pé jọ sí,* síwájú àwọn aṣojú ìjọba àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ tí ẹ máa fi gbèjà ara yín tàbí ohun tí ẹ máa sọ,+ 12 torí ní wákàtí yẹn gan-an, ẹ̀mí mímọ́ máa kọ́ yín ní àwọn ohun tó yẹ kí ẹ sọ.”+

  • Lúùkù 21:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Torí náà, ẹ pinnu lọ́kàn yín pé ẹ ò ní fi bí ẹ ṣe máa gbèjà ara yín dánra wò ṣáájú,+ 15 torí màá fún yín ní àwọn ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ ò ní lè ta kò tàbí kí wọ́n jiyàn rẹ̀.+

  • Ìṣe 4:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ni Pétérù, tí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ bá sọ fún wọn pé:

      “Ẹ̀yin alákòóso àti ẹ̀yin àgbààgbà,

  • Ìṣe 6:9, 10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Àmọ́ àwọn ọkùnrin kan látinú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira wá, pẹ̀lú àwọn ará Kírénè àti àwọn ará Alẹkisáńdíríà àti lára àwọn tó wá láti Sìlíṣíà àti Éṣíà, wọ́n wá bá Sítéfánù fa ọ̀rọ̀. 10 Àmọ́ wọn ò lè dúró níwájú rẹ̀ nítorí ọgbọ́n àti ẹ̀mí tó fi ń sọ̀rọ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́