-
Mátíù 26:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ní ọjọ́ kìíní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n bi í pé: “Ibo lo fẹ́ ká ṣètò fún ọ láti jẹ Ìrékọjá?”+ 18 Ó dáhùn pé: “Ẹ lọ sínú ìlú, kí ẹ lọ bá Lágbájá, kí ẹ sì sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ sọ pé: “Àkókò tí a yàn fún mi ti sún mọ́lé; èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi máa ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ní ilé rẹ.”’” 19 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ohun tí Jésù sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá.
-